Orò Ìbálé Ní Ayé Àtijọ́ Àti Òde Òní


Ẹni tí a bá nílé jẹ́ ènìyàn (ọkùnrin tàbí obínrin) tí kò ní ìbálòpọ̀ rí. Àmọ́ ní awùjọ Yorùba, Ìbálé níí ṣe pẹ̀lú obìnrin ju ọkùnrin lọ. Oǹkọ̀tàn yìí ti kọ àkọsílẹ̀ lóríṣiríṣi lóri ìbálé ní èdè Gẹ̀ẹ́sì, àmọ́ ó nífẹ́ẹ́ láti jẹ́ kí irúfẹ́ àkòrí yìí wà ní àkọsílẹ̀ ní èdè abínibí rẹ̀ tí ń ṣẹ èdè Yorùbá. Ohun tó sì gun ní kẹ́ṣẹ́ ni látí wo pàtàkí ibálé ní ayé àwọn baba ńlá wa àti òde òní.

Ní ayé àtijọ, ìbálé jẹ́ orò kan pàtàkì àti ohun ìwurí fún ọmọbìnrin tí kò tíì relé ọkọ àti àwọn ẹbí rẹ̀ lápapọ̀ tó fi jẹ́ pé ìtìjú ayérayé ní ó má ń jẹ́ fún wúńdíá àti àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ tí ó bá ti tasẹ̀ agẹ̀rẹ̀ nípa ìbálé kí ó tó ó di ọjọ́ ìgbéyàwó. Àmọ́, ní òde òní, ìbàjẹ́ ti di ẹwà, ìbálé ti di ohun ìfà (ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin ló ti di anímáṣahun, èyí ni pé tajá-tẹran ló ti bá wọn láṣepọ̀ láì tíì wọlé ọkọ)

Ní ayé atijọ̀, àṣà ìfọmọfọ́kọ ló gbòde, lẹ́yìn tí ẹbí ọkọ bá ti fojúsóde tí wọ́n ti rí ẹbí tí wọ́n ti fẹ́ fẹ́yàwó, tí wọń sì ti ṣe ìwádìí ẹbí náà dáadáa, ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ ni wíwá Alárinnà. Alárinnà yìí ni ẹni tó ma wà láàárín ẹbí ọkọ àti aya, òun náà sì ni ọmọbìnrin ati ọmọkunrin àfẹ́sọ́nà yóò ma rán sí ara wọn nítorí pé wọn kò tíì ní àǹfààní láti máa bá ara wọn sọ̀rọ̀ tààrà. Alárinnà máa ń sábà jẹ́ ọ̀rẹ ọmọbìnrin tàbí ọmọkunrin àfẹ́sọ́nà yìí. Ìgbeṣẹ̀ kejì ni ‘Ìjẹ́hẹn’. Èyí ni wíwí fún àwọn òbi wọn pé àwọn ti gbà láti fẹ́ ara wọn gẹ́gẹ́ bi lọ́kọláya. lẹ́yìn èyí ni ìtọrọ yóò wáyé. Àsìkò yìí ni ẹbí méjéèjì yóò pàdé tí à ń pè ní mọ̀-mí-n-mọ̀-ọ́, àwọn ẹbí lọ́kọláya yóò mọ ara wọn, àwọn ẹbí ọkọ yóò sì gba ìyọ̀nda láti fẹ́ ọmọbìnrin náà. Nígbà tí ẹbí méjéèjì bá ti gbà láti fi ọmọ fún ara wọn, wọn yóò mú ọjọ́ ìdána, ọjọ́ yìí ni wọn yóò kó gbogbo ẹrù ìdana lọ sílé ẹbí ìyàwó àfẹ́sọ́nà. Ìgbésẹ̀ tó tẹ̀lẹ ni gbígbéyàwó/ìgbéyàwó. Ọjọ́ yìí ni àwọn ẹbí méjéèjì yóò filé pọntí, ti wọn yóò fọ̀nà rokà. Lẹ́yìn gbogbo fẹ̀rẹ̀rẹ̀ ìgbéyawó, àwọn ọ̀rẹ́ ìyàwó àtí àwọn ìyàwó ilé yóò sin ìyàwó tuntun lọ sílé ọkọ rẹ. Ní ẹnu ọ̀nà àbáwọlé ọkọ rẹ̀, àwọn mọ̀lẹ́bí ọkọ rẹ̀ yóò ṣẹ àdúrà fun wọn á sì da omi si lẹ́sẹ̀. Dídami sí aya tuntun lẹ́sẹ̀ nínú àṣà Yorùbá túmọ̀ sí pé kí ilé tuntun yìí rọ̀ ọ́ pẹ̀sẹ̀.

Lẹ́yìn tí ìyàwó ti wọlé ọkọ rẹ̀ tán, lálẹ́ ìgbéyàwó, àwọn ẹbi lọ́kọláya yí ò dúró sí gbàgede fún wíwo ìbálé ìyáwó tuntun. Níbí yìí ni wọn yóò ti mọ bóyá ìyàwó tuntun jẹ́ wúndíá àbí ó ti fi ìbàlé rẹ̀ tàfà. Ọ̀nà ti wọn ń gbà mọ èyí ni ti ọkọ bá mú aṣọ ala tó ní ẹ̀jẹ̀ lára jáde, ó túmọ̀ sí pé ó bá ìyàwó rẹ̀ nílé, wọn kò tíì já ìbálé obìnrin ọ̀ún. Ijó àti ẹyẹ ni fún awọn ẹbí méjéèjì pàápàá jùlọ àwọn ẹbí ìyàwó yìí nítorí ọmọ wọn kò lo ara rẹ̀ nílòkulò. Àwọn ẹbi ìyàwó a gba ohun mèremère bíi apẹ̀rẹ̀ tó kún fún oríṣiríṣi aṣọ, odidi agbè ẹmu, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Àmọ́ bí ó bá jẹ́ pé ọkọ kò ba ìyàwó rẹ̀ ni wúndíá, ó ti di apẹ̀rẹ̀ àjàṣẹ́, àwọn ẹ̀bun tí aya èyí àti àwọn ẹbí rẹ̀ yóò gbà ni àwọn kòròfo agbè ẹmu, kòròfo ìṣáná, àti apẹ̀rẹ̀ tí ìdí rẹ̀ ti já. Ọkọ ọun le kọ aya rẹ ni wakati ọun. Ohun ìtìjú àti ẹ̀tẹ́ ní èyí jẹ́ fún àwọn ẹbí ìyàwó tuntun, lọ́pọ̀ ìgbà, ìtìjú yìí a máa pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí wọn yóò fi ìlú sílẹ̀.

Ní òde òní, ìbálé kò já mọ́ nǹkan mọ́. Ọ̀pọ̀ ọmọbìnrin ló jẹ́ wúńdíá lójú, adélébọ̀ nísàlẹ̀. Púpọ̀ obìnrin tí kò tíì wọlé ọkọ ní òde òní ló ní èròńgbà pé ìbálé jẹ ohun àtijọ́. Àwọn ọkùnrin náà kò tilẹ̀ bìkítà mọ́. Wọ́n ní èrò pé ìtọ́wọ̀ ni à ń madùn ọbẹ̀ èyí tó túmọ̀ sí pé tọkùnrin-tobìnrin ti ń ní àjọṣepọ̀ ṣáájú ọjọ́ ìgbéyàwo.
Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tí òǹkọ̀tàn ṣe jẹ́ kó di mímọ̀ pé oríṣiríṣi nǹkan ló fa ìdí tí ìbálé kó fi jọjú mọ́. Yàtọ̀ sí pé láyé òde òní, ojú àwo ni àwo fi ń gbọbẹ̀ ní èyí tó jẹ pé fúnra àwọn ọ̀dọ́ ni wọ́n ń fẹ́ ìyàwó fúnra wọn. Àmọ́, àwọn obìnrin òde òní tí ọkọ bá bá nílé máa ń sábà fi ìbálé wọn sirègún lórí ọkọ lọ́pọ̀ ìgbà tí èdè àìyedè bá wáyé láàárín wọn. Àwọn obìnrin míràn a sì tún máa fi ìbálé yìí ṣe ìgbéraga sí àwọn ẹbí ọkọ rẹ̀. Àwọn ọkùnrin míràn tilẹ̀ sọ pé bíbá obìnrin nílé kò ní kí obìnrin náà ṣe ìfẹ́ òtítọ́ pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ nígbẹ̀yìn. Onkọ̀tàn wòye pé, àwọn àríwísí yìí kó fẹsẹ̀ múlẹ̀ tó, nítorí náà o rọ́ àwọn obìnrin láti tọ́jú ìbálé wọn nítori ohun ìwúri tí kò lẹ́gbẹ́ ni.

Edited by Mansurah Oritoke Alabi.

Related:

Gbigbọn ilẹ ni Turkey ati Syria- Ijabọ

DONATE

https://selar.co/1rqb

For Advert Inquiries
Tele/+234 7036309859
E-mail: themuslimvoiceng@gmail.com

For News/Article
E-mail: themuslimvoiceng@gmail.com

Have any Question or Comment?

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

error: Content is protected !!
Chat With Our Agent!